Friday, September 24, 2021

Amoran Mi Fun Awon Oje Wewe Onkowe Ni Wipe Ki Won Ni Ifarajin, Iteriba Ati Suuru Pupo – Adepoju Suliyat

 

AMORAN MI FUN AWON OJE WEWE ONKOWE NI WIPE KI WON NI IFARAJIN, ITERIBA ATI SUURU PUPO – ADEPOJU SULIYAT

 


 

Suliyat Adepoju je Alaga fun Egbe Awon Odo Onkowe eyi ti o wa labe Society of Young Nigerian Writers. O tun je omo Egbe Ibadan Book Club. Ninu iforowero pelu Wole Adedoyin, o so nipa iriri re gege bi Oje Wewe Onkowe ti o fe dabi Ojogbo Akiwumi Isola, Oloye Adebayo Faleti ati be be lo.

 

 

WA:  BAWO LOSE BERE? KÍNNI OTI KO ATI WIPE KIN LÓ N KO LOWO?

 

SA:  Mo bere lati ile ẹkọ alakọ bẹrẹ. Mo ti ko ọpọlọpọ ewi ati ere onise akagbadun.  Ere onise miran ni mo n kọ lọwọ eyi ti àkọlé rẹ jẹ ỌMỌ INÚ ỌKÁ

 

WA: KÍNNI IKAN TO WU E LORI TI O FI RO PÉ IWO NAA FE MÁA KO NKAN

 

SA: Èdè abínibí wà lo wumi lori to jẹ kín máa kọ nkan tori mo fẹran asa púpọ̀

 

WA: TANI OUN WO GEGE BI AWO KOSE, ATI WIPE KÍNNI IDI TI ENI NAA FI JE AWOKOSE FÚN E.

 

SA: Baami Aare Kehinde Osuolale (Ọba Afedeyangan) ni eni tí mo n wo gẹgẹ bi awo kọṣe. Ìdí ti eni naa fi jẹ awokọṣe fún mi ni wipe wọn jẹ ẹni tó fẹràn láti máa gbé àṣà abinibi wa ga.

 

WA:  AMORAN WO LO LE GBA AWON OJE WEWE TO SESE BO.

 

SA: Amoran mi fún wọn ní kí wọn ní iteriba,kii won ni ifarajin tori púpọ egbin ni wọn o fi kan wọn amo kii won ní sùúrù Pupọ

 

WA: KÍNNI AWON NKAN TI MÁA N TIE KO NKAN TI N KO YEN.

 

SA: Iriri,iwoye tabi ti eyan ba se ohun to dun mi tabi ohun to dun mọ mi.

 

WA:  SE O NI ILANA TO FI KO NKAN TO N KO,ABI ONI ONA KAN PATO TO N KO NKAN LE LORI?

 

SA: Mi'o ni ilana kan pato ti mo n kọ nkan le lori kosi sí ọna ti mio le kọ nkan le lori.

 

WA:  BAWO LESE BERE? IGBA WO LO BERE? KÍNNI IDI TOFI BERE?

 

SA: Mo bere lati ile ẹkọ alakọ bẹrẹ. O ti le lodun mewaa seyin ti mo bẹrẹ. Mo fe di o gbohun Tarigi ninu onkòwe ti orukọ rẹ oni parẹ titi Lai

 

WA:  ÌWÉ WO LO KOKO GBÉ JADE

 

SA: Ayekusibikan ni iwe ti mo kọkọ gbé jade sori ẹrọ ayelujara (Facebook)

 

WA:  SE ONI NKANKAN PATO TÓ MÁA N FI ISE RE SUN

 

SA: Afojusun mi k'oju kii ayé rí kì wọn kẹ̀kọ́ ni bẹẹ kii emi naa sì dide lati ara bẹẹ

 

WA:  BAWO L'OSE RI NIGBA TÓ N FI AWON NKAN TO N KO S'OWO SITA.

 

SA: Inu mi dun tori Pupọ eda lo tẹwọ gba.

 

WA:  IKAN TO N KO YEN IBO LOTI RI ILANA TO N LO.

 

SA: Ọlọrun ọba lọ fún mi ni ìlànà tí mo n lo,o sì fi ọpọ ẹda jinki mi lati tọmi sónà lori bi máa ṣe lo ìlànà naa.

 

WA: ẸNI TÍ N BO GBÉ ÌWÉ RE JÁDE IBO LETI PADE?

 

SA: Mio ni eni ti bami gbe iwe jade fún ra alara mi ni mo máa n gbe jade sori ẹrọ Ayelujara ( Facebook)

 

WA:  TOBA JU ISE RE SI IGBORO KINNI AWON ESI TO RI LATI ODO ÀWON TÓ N KA

 

SA: Ti mo ba ju isẹ mi sí igboro eyi ni awọn esi ti mo n rí. Opọ ẹda ni máa n fún mi lami kori ya(comment, like, share). Opọ a pèmí wọn a sadura fún mi. Opọ a ní kín fi onka ifowopamọ (account number) s'ọwọ sí àwọn. Opọ ẹlòmíràn a sì jí iṣẹ mi gbe ti won o sì yọ orúkọ mi kuro ninu re ti wọn o sì fi ti wọn sì,eyi a sì máa bami ninu jẹ lọpọ ìgbà

 

WA: BAWO NI AWON EYAN SELE MO E SÍ?

 

SA: Awọn eyan le mosi nipa mi  nipa kii won pèmí sori ẹrọ ibanisọrọ mi tabi ki wọn kan simi lori ero ayelujara Facebook ati Whatsapp.

 

WA: KÍNNI OGBON TÓ N TASI,TI WU AYÉ LORI TI AYE FI GBA ITAN RE

 

SA: Adun,oyin,ohun to wa ninu iwe to n fa olukawe mora lati ni ife si iwe naa ni kika.

 

WA: SE IWO NAA MO AWON ASISE KEKEKE TI AWON ONKOWE TO SESE BERE MÁA N SE.

 

SA: Awọn aṣiṣe wọn ni yii: Won kii ni iteriba fún agba iwaju won rara. Pupo miran kii kọ ìtàn wọn tan abo iṣẹ ni won máa ju sita.

 

WA: EWO NINU AWON ITAN RE LO GBÁDÙN NI KIKO JU

 

SA: ARIKẸ ASEGITA

 

WA: ÌWÉ TO KOKO GBÉ JADE KÍN LÓ SO NÍPA RE,BAWO NI IRIN AJO GBIGBE IWE NÁÀ JADE SERI

 

SA: Ayekusibikan ni iwe ti mo kọkọ kọ sí ori ẹrọ ayelujara Facebook ti mo ṣì jẹ kii ọpọ mọ pé àwọn kan ti wọn fojú tẹ n belu nínú ayé púpọ ni o ṣe fojú tẹnbelu. Irin àjò iwe náà kole rara bo sie jẹ pé ojú kọkọ timi amo nigba todi itewo gba inu mi dun.

 

WA: KÍNNI AWON ISE TI O N FI IWE NÁÀ RÁN SÍ ÀWÙJO

 

SA: Ki ayé leri ẹkọ kọ ni awọn iṣẹ ti mo fi ran sie ta.

 

WA: BAWO L'ASE LERI E LORI AYELUJARA

 

SA: Facebook: Arike Elewi Omo Oba

No comments:

Post a Comment