Friday, December 17, 2021

Ewi Ni Mo Gbadun Ju Lati Ma Ko - Olujide Jacob Olúmofe

 

EWI NI MO GBADUN JU LATI MA KO - OLUJIDE JACOB OLÚMOFE

 


Olujide Jacob Olúmofe je okan lara omo egbe Ibadan Book Club. Ninu iforowero pelu Wole Adedoyin, o so nipa iriri re gegebi Onkowe

 

WA:  BAWO LOSE BERE? KÍNNI OTI KO ATI WIPE KIN LÓ N KO LOWO?

 

OJO: Ó pẹ́ tí mo ti bẹ̀rẹ̀. Ọ̀nà àkọ́kọ́ ni pé mo pinnu. Mi ò tíì kọ ìwé kankan síta ṣùgbọ́n mo ni àwọn iṣẹ́ kéèkèé kan ti mo ti kọ. Àwọn kan jẹ́ Ewì: Àpẹrẹ: Láyípo Layé.. Àwọn kan, Ọ̀rọ̀ Ìyànjú (motivational talks) ní gẹ̀ẹ́sì àti ní Yorùbá: Appreciation..

 

WA: KÍNNI IKAN TO WU E LORI TI O FI RO PÉ IWO NAA FE MÁA KO NKAN

 

OJO: Ohun tó wúmi lórí ni pé mo ní àwọn iṣẹ́ tí mo fẹ́ẹ́jẹ́ láùjọ ènìyàn nípa èyí tí mo fẹ́ la àwọn ipa rere.

 

WA: TANI OUN WO GEGE BI AWO KOSE, ATI WIPE KÍNNI IDI TI ENI NAA FI JE AWOKOSE FÚN E.

 

OJO: Àwọn aláwòṣeè mi pọ̀ o, látorí àwọn òbíì mi, àyíká, ilé-ẹ̀kọ́ ìwé, ilé-ìjọsìn ṣọ́ọ́ṣì, gbígbọ́ àwọn ètò kan lóríi rédíò àti tẹlifíṣàn abbl.

 

WA:  SE ONI NKANKAN PATO TÓ MÁA N FI ISE RE SUN

 

OJO:  Àwọn ọ̀rọ̀ ìrètí, ìṣítí abbl

 

WA:  AMORAN WO LO LE GBA AWON OJE WEWE TO SESE BO.

 

OJO: Kí wọ́n pinnu, kí wọ́n sọ fún Ọlọ́run, kí wọ́n jẹ́ kí Ọlọ́run pèsèe wọn torí gbogbo nǹkan ló ní kíkọ́.

 

WA:  SE O NI ILANA TO FI KO NKAN TO N KO,ABI ONI ONA KAN PATO TO N KO NKAN LE LORI?

 

OJO: Mo nílànà. Lọ́wọ́ lọ́wọ́, ìlànà Báyọ̀ Fálétí àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùmi Ìṣọ̀lá ní mò ń lò.

 

WA:  BAWO LESE BERE? IGBA WO LO BERE? KÍNNI IDI TOFI BERE?

 

OJO:  Ọdún yẹn ti pẹ́. Mo kàn ṣáàmọ̀ pé bí kiní ọ̀hún bá dé sími, kìí ṣe wèrè o. Ẹ̀mí Ìmísí Ọlọ́run ni. Tí ó bá ti dé, mi ò kíì le ṣe nǹkan míràn àfi tí nbá kọ ohun tó fẹ́ kí nkọ. Ìmísí àti Ìpinnu.

 

WA:  ÌWÉ WO LO KOKO GBÉ JADE

 

OJO: Mi ò tíì gbé ìwé jáde.

 

WA:  TOBA JU ISE RE SI IGBORO KINNI AWON ESI TO RI LATI ODO ÀWON TÓ N KA

 

OJO: Wọ́nní bórin dùn bí ò dùn, ẹni tan wò máa wí. Àwọn èèyàn tó yímika ni mo máa n kéwì tàbí ka iṣẹ́ mi létíi wọn. Wọn a sì ṣàríwísí si.

 

WA: BAWO NI AWON EYAN SELE MO E SÍ?

 

OJO: Lágbára Ọlọ́run, kò sí ìgbà tí àwọn èèyàn fẹ́ mọ̀mí tí mi ò níí ṣetán láti dáhùn.

 

WA: KÍNNI OGBON TÓ N TASI,TI WU AYÉ LORI TI AYE FI GBA ITAN RE

 

 OJO: Kò lọ́gbọ́n ju ki n ṣàkójọ iṣẹ́ẹ̀ mi lọ́nà tí ó ṣeé gbà nílànà Yorùbá àkọtán òde-òní.

 

WA: SE IWO NAA MO AWON ASISE KEKEKE TI AWON ONKOWE TO SESE BERE MÁA N SE.

 

OJO:  Mo mọ̀ lará ẹ̀.

 

WA: EWO NINU AWON ITAN RE LO GBÁDÙN NI KIKO JU

 

OJO:  Kò sí iṣẹ́ mi tí nkò gbádùn. Ṣùgbọ́n Ewì ni mo gbádùn jù lọ́wọ́ lọ́wọ́.

 

 WA: KÍNNI AWON ISE TI O N FI IWE NÁÀ RÁN SÍ ÀWÙJO

 

 OJO:  Àwọn iṣẹ́ tí mò ń rán sáùjọ ènìyàn ni pé kámá wayé máyà. Ká má fayé ni ọmọnìyàn lára. Ká jẹ́ kí ìṣèjọba tu tẹrútọmọ lára abbl.

 

WA: BAWO L'ASE LERI E LORI AYELUJARA

 

OJO: Lóríi Facebook àti Instagram, Olúmofe Olujide Jacob. Ẹ ṣeun. Ire ò.

No comments:

Post a Comment